The slanderers hasten on both sides of her, and their saying:
Àwọn ẹlẹgàn ń sáré ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ méjèèjì, ọ̀rọ̀ wọn sì ni:
"Indeed you, O son of Abū Sulmā, are surely to be killed."
"Nítòótọ́, ìwọ ọmọ Bàbá Sulmā, wọn yóò pa ọ́."
And every close friend whom I had hoped in said:
Gbogbo ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí mo ti ní ìrètí nínú rẹ̀ sì sọ pé:
"I will surely not entertain you, for I am occupied away from you."
"Èmi kò ní bá ẹ́ sọrọ, nítorí pé dájúdájú èmi kò ráyè fún ọ́."
So I said: "Clear my path — may you be bereft of your father!
Mo sì sọ pé: "Ẹ yàgo kúrò lọnà mí— kí ẹ̀yin má ní bàbá!
For everything the Most Merciful has decreed is surely done."
Nítorí gbogbo ohun tí Ọlọ́run Àlàánú bá ti pinnu ni yóò wà sí ìmúṣẹ́."
Every son of a woman, though his safety be prolonged,
Gbogbo ọmọ tí obìnrin bá bí, bí ààbò rẹ̀ bá tilẹ̀ gùn,
One day will be carried upon a curved bier.
Ní ọjọ́ kan, a ó gbé e sórí àga ìsìnkú tí ó tẹ̀.
I was informed that the Messenger of Allah has threatened me,
Wọn sọ fún mi pé Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ti halẹ̀ mọ́ mi,
But forgiveness from the Messenger of Allah is to be hoped for.
Ṣùgbọ́n àforíjì lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni a ń retí.