Chapter 5

الْمَقَامَةُ الْكُوفِيَّةُ

1

حكى الحارثُ بن همّامٍ قال: سمرت بالكوفَةِ في ليلَةٍ أديمها ذو لونين.ِ


English

Al-Harith bin Hammam narrated: I spent an evening in Kufa on a night whose sky was of two colors.

Yoruba

Hárìsù ọmọ Hammámì sọ̀rọ̀ pé: Mo lo alẹ́ kan ní ìlú Kúfà, ní òru tí àwọ̀n òfúrufú rẹ̀ jẹ́ oníbejì.

2

وقمرها كتعويذٍ من لُجين.ٍ


English

And its moon was like an amulet of silver.

Yoruba

Òṣùpá rẹ̀ sì dàbí ọ̀pá àsẹ̀ tí a fi fàdákà ṣe.

3

مع رفقَةٍ غُذوا بلِبانِ البيان.ِ


English

With a group nourished by the milk of eloquence.

Yoruba

Pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ tí a bọ́ pẹ̀lú ọmú ọgbọ́n ọ̀rọ̀.

4

وسحبوا على سحبانَ ذيلَ النسيان.ِ


English

Who dragged the tail of oblivion over Sahban.

Yoruba

Tí wọ́n fà ìrù ìgbàgbé lórí Sahaban.

5

ما فيهِم إلا من يحفَظُ عنه ولا يتحفَّظُ منه.


English

Among them was none but who that can be gained from and not guard against

Yoruba

Kò sí ẹnìkan nínú wọn àyàfi ẹni tí wọ́n yóò ri àǹfààní rẹ tí kí ṣe ẹni a ṣọ́ra fún.

6

ويميلُ الرفيق إليهِ ولا يميلُ عنه.


English

And companion do incline towards him and not turn away from.

Yoruba

Ẹni ọrẹ a má fẹ́ràn níwọ̀n tí kì ṣe ẹnì a sáà fún

7

فاستهوانا السمر. إلى أنْ غرب القمر.


English

We were captivated by the night talk until the moon set.

Yoruba

A ní inú dídùn sí ìsọ̀rọ̀ alẹ́ títí tí òṣùpá fi wọ̀.

8

وغلَب السهر.


English

And sleeplessness prevailed.

Yoruba

Àìsùn sì borí wa.

9

فلما روق الليلُ البهيم. ولمْ يبق إلا التهويم.


English

When the dark night cleared, and only drowsiness remained.

Yoruba

Nígbà tí òru dúdú mọ́, tí kò sí ohun tó kù bí kò ṣe oorun.

10

سمِعنا من البابِ نبأةَ مستنبِح.ٍ ثمّ تلَتها صكّةُ مستفْتِح.ٍ


English

We heard from the door the bark of one seeking, then followed by the knock of one requesting entry.

Yoruba

A gbọ́ gìgbó ajá láti ẹnu-ọ̀nà, lẹ́yìn èyí ni a gbọ́ ìkànlẹkùn ẹni tí ó fẹ wọlé.

© , Qatru