The Sanjari Maqama
Ìtàn Sanjari
Al-Harith ibn Hammam narrated: Once before, I had returned from Sham heading towards the City of Salaam with a caravan from Banu Namir and a group that has goodness and foods.
Hárìsù ọmọ Hammam sọ pé: Lẹ́ẹ̀kan rí, mo padà láti Sham sí Ìlú Salaamu pẹ̀lú àwọn arìnrìn-àjò kan láti Banu Namir àti ẹgbẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rere àti oúnjẹ
With us was Abu Zayd el-Saruji, the control of the hasty, the solace of the bereaved, the wonder of the time, and the one pointed to with fingers in eloquence.
Pẹ̀lú wa ni Abu Seidu ara ilu Saruji, olùdarí àwọn oluyara, ìtùnú olupadanu ọmọ, ìyàlẹ́nu àwọn ìgbà, àti ẹni tí wọ́n ń tọ́ka sí pẹ̀lú ọwọ́ nínú àlàyé mímọ
We arrived in Sinjar where a merchant hosted a feast and invited both the city dwellers and the nomads.
A dé Sinjar lásìkò tí oníṣòwò kan ṣe àpéjọ̀ àti pé ó ṣe ìkéde gbogbogboo fun àwọn ará ìlú àti àwọn ará igberiko láti wà jẹun
His invitation reached the caravan, combining the obligatory and the voluntary.
Ìpé rẹ̀ dé àwùjọ náà, tí ó kójọ papọ̀ lórí àwọn ohun tí ó jẹ́ dandan àti àwọn ohun tí kó jẹ́ dandan.
When we answered his call and entered his hall, he brought forth foods that sweetened the mouth and pleased the eye.
Nígbà tí a dáhùn ìpé rẹ̀ àti tí a wọ inú ilé rẹ̀, ó mú àwọn oúnjẹ tí ó dùn fún ẹnu àti tí ó wù yì fún ojú.
Then he presented a dish as if it were solidified from air, gathered from dust, crafted from the light of space, or peeled from a white pearl.
Lẹ́yìn náà, ó fi àwo kan hàn tí ó dàbí ẹni pé ó di láti inú afẹ́fẹ́, tàbí ó kó jọ láti inú erùpẹ̀, àbí ó ṣe láti inú ìmọ́lẹ̀ òfurufú, àbí tí ó bó láti ara pẹrili funfun.
And it was placed with the folds of bliss.
Ó sì ti ko sínú rẹ oríṣi ìgbádùn.
And perfumed with abundant fragrance.
Ó sì kó ẹwà bá pẹ̀lú òórùn aládùn.
And a drink from Tasneem was brought to him.
Wọ́n sì mú omi láti Tasneem wá fún un.