English: O Allah, we praise You for what You have taught of eloquence and inspired of clarity.
Yoruba: Ọlọ́hun, a yín Ọ fún ohun tí O ti kọ́ni nípa ọ̀rọ̀ mimo àti ohun tí O fí nù wá nípa àlàyé.
English: We also praise You for the abundance You have bestowed and the protection You have provided.
Yoruba: A tún yín Ọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí O ti fún wa àti ààbò tí O ti pèsè.
English: We seek refuge in You from excessive speech and useless talk.
Yoruba: A wá ààbò lọ́dọ̀ Rẹ kúrò nínú ọ̀rọ̀ àsójù àti ọ̀rọ̀ asán.
English: As we seek refuge in You from the shame of stammering and the disgrace of being tongue-tied.
Yoruba: Bí a ti ń wá ààbò lọ́dọ̀ Rẹ kúrò nínú ìtìjú kíkọ́sẹ̀ àti ìdójútì àìlè sọ̀rọ̀.
English: We ask Your sufficiency against being charmed by praise or being lenient with the forgiving.
Yoruba: A bẹ̀ Ọ́ fún ìtọ́jú kúrò nínú ìtànjẹ oluyìn àti ìfàyàbálẹ̀ pẹ̀lú oludariji ni
English: As we seek Your protection against standing up to slander or exposing the disgraced.
Yoruba: Bí a ti ń wá ìdáàbòbò Rẹ kúrò nínú dídìde sí ẹ̀gàn tàbí titu àṣírí ẹni tí a ti dójútì.
English: We seek Your forgiveness for driving desires to the market of doubts.
Yoruba: A tọrọ ìdáríjì Rẹ fún didari ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ sí ọjà iyèméjì.
English: As we seek Your forgiveness for taking steps towards sinful plans.
Yoruba: Bí a ti ń tọrọ ìdáríjì Rẹ fún gbígbé ìgbésẹ̀ sí awon ètò ẹ̀ṣẹ̀.
English: We ask You for guidance leading to righteousness and a heart that turns with the truth.
Yoruba: A bẹ̀ Ọ́ fún ìtọ́sọ́nà tí ó ń darí eyan sí òdodo àti ọkàn tí ó ń yí pẹ̀lú òtítọ́.
English: And a tongue adorned with truthfulness and speech supported by evidence.
Yoruba: Àti ahọ́n tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú òtítọ́ àti ọ̀rọ̀ tí a fi múlẹ̀ pẹ̀lú ẹrí.