English: And you prioritize love for a garment you desire over a reward you should purchase
Yoruba: O sì fi ìfẹ́ aṣọ tí o fẹ́ síwájú ju èrè tí o ye ki o rà lọ
English: The rubies of connections are dearer to your heart than the times of prayer
Yoruba: Àwọn ọ̀ṣọ́ ìdàpọ̀ ṣe pàtàkì sí ọkàn rẹ ju àkókò àdúrà lọ
English: And exaggeration in gifting ladies is more preferable to you than consistency in charity
Yoruba: Àṣejù nínú fifun omidan lowo ṣe pàtàkì sí ọ ju ìṣesí déédé nínú ìtọrẹ lọ
English: And plates of various colors
Yoruba: Àti àwọn àwo alawo orisirisi
English: More desirable to you than the pages of religions
Yoruba: O fẹ́ jú àwọn ìwé ẹ̀sìn lọ
English: And the jest of peers is more pleasant to you than the recitation of the Quran!
Yoruba: Ẹ̀rín pelu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ sì dùn mọ́ ọ ju kíka Kùráánì lọ!
English: You command what is right yet violate its sanctuary
Yoruba: O ń pàṣẹ ohun tí ó tọ́ síbẹ̀ o ń tẹ̀ ogba rẹ mọ́lẹ̀
English: And you defend against the wrong yet do not avoid it!
Yoruba: O sì ń kọ fun awon eeyan lati se ohun tí kò dára síbẹ̀ o kò yẹra fún un!
English: You distance yourself from injustice then embrace it
Yoruba: O ń gbe abosi jìnnà sí ara re lẹ́yìn náà o ko si
English: And you fear people while Allah is more deserving that you fear Him!
Yoruba: O sì ń bẹ̀rù ènìyàn nígbà tí Ọlọ́hun ló yẹ kí o bẹ̀rù rẹ̀ jù!