English: seeking heavy rain and light drizzle,
Yoruba: tí ó ń wá òjò àrà àti erì,
English: and consoling myself with 'maybe' and 'perhaps'.
Yoruba: tí ó sì ń tù ara rẹ̀ nínú pẹ̀lú 'bóyá' àti 'ó ṣe é ṣe'.
English: When I arrived at Hulwan,
Yoruba: Nígbà tí mo dé Ḥulwán,
English: having tested brothers,
Yoruba: lẹ́yìn tí mo ti dán àwọn arákùnrin wò,
English: probed measures,
Yoruba: Ti mo sì tún wádìí àwọn òsùwọ̀n,
English: and experienced what disgraces and adorns,
Yoruba: kí n sì ní ìrírí ohun tí ó ń ba ni jẹ́ àti èyí tí ó ń ṣe ọ̀ṣọ́,
English: I found there Abu Zayd as-Saruji, shifting between forms of affiliation,
Yoruba: Mo rí Abú Seidu omo ilu Sarújì níbẹ̀, tí ó ń yí padà láàárín àwọn ọ̀nà ìbágbépọ̀,
English: and stumbling through means of acquisition.
Yoruba: tí ó sì ń kọsẹ̀ láàárín àwọn ọ̀nà ìjẹ àti mímú,
English: Sometimes he would claim to be from the family of Sasan,
Yoruba: Nígbà míràn yóò máa sọ pé ó wá láti ìdílé Sásán,
English: and other times he would trace his lineage to the chiefs of Ghassan.
Yoruba: nígbà míràn yóò sì máa ṣàfihàn pé ó jẹ́ ọmọ àwọn olórí Ghassán.