English: Al-Harith bin Hammam said: When he captivated us with the sweetness of his speech.
Yoruba: Hárìsù ọmọ Hammámì sọ pé: Nígbà tí ó fi adùn ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbá wa lọ́kàn.
English: And we knew what was behind his lightning.
Yoruba: A sì mọ ohun tí ó wà lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná rẹ̀.
English: We hastened to open the door.
Yoruba: A yára láti ṣí ìlẹ̀kùn.
English: And we received him with welcome.
Yoruba: A sì fi inú dídùn gbà á.
English: And we said to the boy: Come on, come on. And bring what is prepared!
Yoruba: A sì sọ fún ọmọdé náà pé: Yára, yára. Kí o sì mú ohun tí a ti pèsè wá!
English: The guest said: By Him who brought me to your threshold.
Yoruba: Àlejò náà sì wí pé: Ní orúkọ Ẹni tí ó mú mi wá sí ẹnu-ọ̀nà yín.
English: I will not taste your hospitality.
Yoruba: N kò ní tọ́wọ́ bọ oúnjẹ yín.
English: Unless you guarantee me that you will not consider me a burden.
Yoruba: Àyàfi tí ẹ bá ṣèlérí pé ẹ kò ní kà mí sí bùkátà,
English: And that you will not trouble yourselves with preparing food for me.
Yoruba: Àti pé ẹ kò ní ṣe wàhálà láti pèsè oúnjẹ fún mi.
English: For many a meal has troubled the eater.
Yoruba: Nítorí ọ̀pọ̀ oúnjẹ ni ó ti fa ìyọnu fún ajẹun.