When my companions prepared and the agreement was settled.
Nígbà tí àwọn èèyàn mi ṣe tán ìmúra, tí ìṣọ̀kan tí múlẹ̀.
We hastened the journey without taking a guide.
A bẹrẹ ìrìn-àjò náà láìsí àtọnà
We asked him from every tribe, and employed a thousand tricks to find him.
A béèrè fún ní gbogbo ìdílé, a sì ló gbogbo ọgbọ́n láti wá a.
But he was hard to find among the tribe, until we thought he was not among the living.
Síbẹ̀síbẹ̀ o ṣòro láti rí nínú àwọn ìran náà, títí a fi rò pé kò sí nínú àwọn alààyè mọ
The travelers were bewildered by his absence, and they sought advice at the gate of Jeroun.
Àwọn ọkan àwọn arìnrìn-àjò ṣe ìyàlẹ́nu nípa àìrí rẹ̀, wọn sì lọ ẹnu-ọ̀nà ilẹ̀ Jeroni làti gbá ìmọ̀ràn,
They continued between tying and untying, between plaiting and twining, until their whispering ceased and the hopeful despaired.
Wọ́n ń gbìyànjú láàárín dídì àti títú, láàárín lilọ àti siso, títí tí itakurọsọ dópin, tí oníreti sì jákàn .
And opposite them, was a person with an appearance of a youth, dressed like a monk, holding a woman’s rosary.
Ní iwájú wọn ni ẹnikan pẹ̀lú ìrísí ọdọ , wọ àṣò wòlíì, o sì mú tẹsùbà obìnrin lọwọ,
And in his eyes was the translation of intoxication.
Nínú ojú rẹ̀ ni ìtumọ̀ ìhun rírà ẹmi wà.
He had centered his gaze on the group
Ó di ojú rẹ̀ mọ àwọn èèyàn náà
And sharpened his ear to eavesdrop.
Ó sì dẹ etí rẹ̀ láti ji gbọ́ àwọn ọrọ wọn