O Allah, You who revive the remains, who ward off calamities, who protect from fears, who are generous in reward, who are the refuge of the destitute, and the guardian of forgiveness and well-being.
Ọlọ́run, Iwọ tó ń gbé egungun èèyàn dìde, tó ń da àjálù dúró, tó ń pa ìbẹ̀rù mọ́, tó ń ṣe apọnle nibi èrè tọ́kantọkan, tó jẹ́ ibi ààbò fún àwọn aláìní, tó sì jẹ́ olúwa ìdáríjì àti àláàfíà.
Send blessings upon Muhammad, the seal of Your prophets, the bearer of Your messages, and upon the lamps of his family, and the keys to his victory.
Fi ibùkún rẹ̀ fún Muhammad, ìkẹ̀yin àwọn wòlíì rẹ, ẹlẹ́rìí àwọn ìroyìn rẹ, àti sí àwọn atupa ẹbí rẹ, àti sí àwọn kókọ́rọ̀ ìṣẹ́gun rẹ.
And protect me from the whispers of devils, the excesses of rulers, the oppression of aggressors, the trials of tyrants, the enmity of enemies, the attacks of adversaries, and the dominance of the overpowering.
Ẹ máa ṣọ́ mí kúrò lọwọ àwọn ìdámọ̀rán àwọn èṣù, àwọn ilọjú àwọn alákòso, ìkà àwọn apanirun, àwọn ìwà ìṣe àìnífẹ́ àwọn ajagun gbalẹ, ìja àwọn ọ̀tá, àti ìjọba àwọn alágbára.
And from the robbery of thieves, the schemes of deceivers, and the treachery of the assassins.
Àti láti ọwọ́ àwọn olè, àwọn ète eletekete, àti àwọn agbára agbenipa.
And protect me, O Allah, from the injustice of neighbors and the company of the wrongdoers.
Ẹ máa ṣọ́ mí, Ọlọ́run, kúrò lọwọ ojoro awọn aládùúgbò àti gbígbé pẹ̀lú àwọn olojoro
And hold back the hands of the oppressors from me, and deliver me from the darkness of the wrongdoers.
Ẹ máa dẹ́ àwọn ọwọ́ àwọn olùṣetàn kúrò lórí mi, kí ẹ sì gba mí kúrò nínú òkùnkùn àwọn aláìṣedéédé.
And by Your mercy, admit me among Your righteous servants.
Pẹ̀lú àánú rẹ̀, fi mí sí ààrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tíwọ́n jẹ èèyàn rere.
O Allah, protect me in my land, in my exile, in my absence, in my return, in my foraging, in my returning from it, in my dealings and returning from it, in my risk and turning from it.
Ọlọ́run, ẹ ṣọ́ mí ní ilẹ̀ mí, ní ìrìn-àjò mí, ní àìsí mí, ní ipadà mí, nígbati mo bá lọfun ẹran mi lounjẹ loko , àti ìpadà mí, níbi títà mí ati ìkórè, ní èwù igbésí ayé mi àti ní bíbọ mí.
And preserve me in my soul, my possessions, my honor and my goods, my reputation and my count, my abode and my surroundings, my state and my wealth, and my destiny.
Ẹ máa ṣọ́ mi nínú ọkàn mí, ní àwọn ohun-ini mí, iyì ati ọlà mí, nínú orúkọ mi àti onka mi, nínú ibùdó mí àti àdúgbò mí, ní àgbègbè mí ati ayé mi, àti nínú àwọn ohun èlò mi, àti kádàrá mí,
And do not let any change befall me, and do not impose on me a changer.
Ẹ má ṣe jé kí a padà sí aburú kòdé bámí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ má ṣe dẹ alaburu sí mí