To whom we are close to through supplication.
Ẹni tí á sún mọ́ nípasẹ̀ àdúrà.
The whom we seek to fulfill our hopes.
Ẹni a má ń rókàn sí latí mú ìrètí ṣẹ.
Who ordained legal charity from wealth.
Ẹni tí ó pàṣẹ fún yíyọ Sáárá òranyàn nínú owó.
And forbade the withholding of questions.
Ó sì pé kí a má ṣe dá àwọn ìbéèrè dúró.
And encouraged the support of the distressed.
Ó sì kéde nípa ìtìlẹ́yìn àwọn tí wọ́n wà nínú ìpọnjú.
And commanded the feeding of the content and the needy.
Ó sì pàṣẹ fún fífún àwọn tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn àti àwọn tí wọ́n nílò nínú oúnjẹ.
And described His close servants.
Ó sì ṣàpèjúwe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó sún mọ́.
In His clear book.
Nínú ìwé Rẹ̀ tó hàn.
And He said, and He is the most truthful of speakers.
Ó sì sọ, ó sì jẹ́ ẹni tí ó sọ òtítọ́ jùlọ nínú àwọn tí ó ń sọ̀rọ̀.
And those in whose wealth there is a known right.
Àwọn tí wọ́n ṣe wípé nínú owó wọn, ní ẹ̀tọ́ tí a mọ̀ wà.