And I traveled all night, traversing the desert, passing every tree and barren land.
Mo rìn gbogbo òru, mo kọjá aginjù, mo kọjá gbogbo igi àti ilẹ̀ tí kò ní ohunkóhun.
Until the morning spread its banners and the caller called to prayer.
Títí tí òwúrò fi tan àsìá rẹ̀, tí olùkéde sì kéde sí àdúrà.
So I dismounted from my steed to perform the obligatory prayer.
Nítorí náà, mo sọ̀kalẹ̀ láti orí ẹṣin mi láti ṣe àdúrà tí ó jẹ́ dandan.
Then I mounted it again and fled from its fatigue.
Lẹ́hìn náà, mo tún gun un, mo sì sá kúrò ní ìrèwèsì rẹ̀.
And I traveled, seeing no trace but followed it, no height but ascended it, no valley but crossed it.
Mo sì rìn, kò sí àfihàn (orípa )kankan tí mo rí àfi pé mo tẹ̀lé e, kò sí ibi gíga kankan tí mo rí àfi pé mo gùn un, kò sì sí àfonífojì kankan tí mo rí àfi pé mo kọjá a.
Nor did I see a rider but I inquired of him.
Kò sì sí ẹlẹ́ṣin kankan tí mo rí àfi pé mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
And my effort was in vain, finding no trace of my goal.
Ìsapá mi sì lọ lásán, kò sì rí àfihàn ibi tí mo ń lọ.
Until the blinding heat struck, and the scorching sun distracted even the strongest.
Títí tí ooru tí ó ń dijú bá mi, tí oòrùn tí ń jó sì kọ̀dí àwọn tí ó lágbára jù lọ.
It was a day longer than the shadow of a spear and hotter than the tears of the bereaved.
Ó jẹ́ ọjọ́ tí ó gùn jù ojiji ọ̀kọ̀ lọ, tí ó sì gbóná jù omije àwọn tí ó pàdánù ọmọ lọ.
So I realized that if I did not rest from the heat and recover with sleep, fatigue would overcome me and my strength would fail.
Nítorí náà, mo mọ̀ pé tí mo kò bá sinmi láti inú ooru àti láti tún ara mi ṣe pẹ̀lú oorun, ìrèwèsì yóò ba mi, agbára mi yóò sì sọnù.